Yoruba Bible

ÌWÉ ÒWE
Chapter 1 of 31
left-arrow Chapter - 1 right-arrow
Verse 1

OWE Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli;

Verse 2

Lati mọ̀ ọgbọ́n ati ẹkọ́; lati mọ̀ ọ̀rọ oye;

Verse 3

Lati gbà ẹkọ́ ọgbọ́n, ododo, ati idajọ, ati aiṣègbe;

Verse 4

Lati fi oye fun alaimọ̀kan, lati fun ọdọmọkunrin ni ìmọ ati ironu.

Verse 5

Ọlọgbọ́n yio gbọ́, yio si ma pọ̀ si i li ẹkọ́; ati ẹni oye yio gba igbimọ̀ ọgbọ́n:

Verse 6

Lati mọ̀ owe, ati ìtumọ; ọ̀rọ ọgbọ́n, ati ọ̀rọ ikọkọ wọn.

Verse 7

Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ; ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọ́n ati ẹkọ́.

Verse 8

Ọmọ mi, gbọ́ ẹkọ́ baba rẹ, ki iwọ ki o má si kọ̀ ofin iya rẹ silẹ:

Verse 9

Nitoripe awọn ni yio ṣe ade ẹwà fun ori rẹ, ati ọṣọ́ yi ọrùn rẹ ka.

Verse 10

Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ̀ ba tàn ọ, iwọ má ṣe gbà.

Verse 11

Bi nwọn wipe, Wá pẹlu wa, jẹ ki a ba fun ẹ̀jẹ, jẹ ki a lugọ ni ikọkọ de alaiṣẹ̀ lainidi.

Verse 12

Jẹ ki a gbe wọn mì lãye bi isà-okú; ati awọn ẹni-diduroṣinṣin bi awọn ti nlọ sinu iho:

Verse 13

Awa o ri onirũru ọrọ̀ iyebiye, awa o fi ikogun kún ile wa:

Verse 14

Dà ipin rẹ pọ̀ mọ arin wa; jẹ ki gbogbo wa ki a jọ ni àpo kan:

Verse 15

Ọmọ mi, máṣe rìn li ọ̀na pẹlu wọn: fà ẹsẹ rẹ sẹhin kuro ni ipa-ọ̀na wọn.

Verse 16

Nitori ti ẹsẹ wọn sure si ibi, nwọn si yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ.

Verse 17

Nitõtọ, lasan li a nà àwọn silẹ li oju ẹiyẹkẹiyẹ.

Verse 18

Awọn wọnyi si ba fun ẹ̀jẹ ara wọn; nwọn lumọ nikọkọ fun ẹmi ara wọn.

Verse 19

Bẹ̃ni ọ̀na gbogbo awọn ti nṣe ojukokoro ère; ti ngba ẹmi awọn oluwa ohun na.

Verse 20

Ọgbọ́n nkigbe lode; o nfọhùn rẹ̀ ni igboro:

Verse 21

O nke ni ibi pataki apejọ, ni gbangba ẹnubode ilu, o sọ ọ̀rọ rẹ̀ wipe,

Verse 22

Yio ti pẹ tó, ẹnyin alaimọ̀kan ti ẹnyin o fi ma fẹ aimọ̀kan? ati ti awọn ẹlẹgàn yio fi ma ṣe inudidùn ninu ẹ̀gan wọn, ati ti awọn aṣiwere yio fi ma korira ìmọ?

Verse 23

Ẹ yipada ni ibawi mi; kiyesi i, emi o dà ẹmi mi sinu nyin, emi o fi ọ̀rọ mi hàn fun nyin.

Verse 24

Nitori ti emi pè, ti ẹnyin si kọ̀; ti emi nà ọwọ mi, ti ẹnikan kò si kà a si:

Verse 25

Ṣugbọn ẹnyin ti ṣá gbogbo ìgbimọ mi tì, ẹnyin kò si fẹ ibawi mi:

Verse 26

Emi pẹlu o rẹrin idãmu nyin; emi o ṣe ẹ̀fẹ nigbati ibẹ̀ru nyin ba de;

Verse 27

Nigbati ibẹ̀ru nyin ba de bi ìji, ati idãmu nyin bi afẹyika-ìji; nigbati wahala ati àrodun ba de si nyin.

Verse 28

Nigbana ni ẹnyin o kepè mi, ṣugbọn emi kì yio dahùn; nwọn o ṣafẹri mi ni kùtukùtu, ṣugbọn nwọn kì yio ri mi:

Verse 29

Nitori ti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa.

Verse 30

Nwọn kò fẹ ìgbimọ mi: nwọn gàn gbogbo ibawi mi.

Verse 31

Nitorina ni nwọn o ṣe ma jẹ ninu ère ìwa ara wọn, nwọn o si kún fun ìmọkimọ wọn.

Verse 32

Nitoripe irọra awọn alaimọ̀kan ni yio pa wọn, ati alafia awọn aṣiwere ni yio pa wọn run.

Verse 33

Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fetisi mi yio ma gbe lailewu, yio si farabalẹ kuro ninu ibẹ̀ru ibi.

Chapter -
1